Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní aginjù. O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì, gẹ́gẹ́ bí òjìji kurukuru ṣe ń dín ooru kù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.

Isaiah 25:5 in English

Isaiah 25:5 · Berean Standard Bible

like heat in a dry land. You subdue the uproar of foreigners. As the shade of a cloud cools the heat, so the song of the ruthless is silenced.

Context

3Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóò bọ̀wọ̀ fún ọ; àwọn ìlú orílẹ̀-èdè aláìláàánú yóò bu ọlá fún ọ. 4Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòṣì ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njú rẹ̀ ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru. Nítorí pé èémí àwọn ìkà dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri 5àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní aginjù. O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì, gẹ́gẹ́ bí òjìji kurukuru ṣe ń dín ooru kù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́. 6Ní orí òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò ti pèsè àsè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn àpèjẹ ti ọtí wáìnì àtijọ́ ti ẹran tí ó dára jù àti ti ọtí wáìnì tí ó gbámúṣé. 7Ní orí òkè yìí ni yóò pa aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn, abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.