Isaiah 25:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóò bọ̀wọ̀ fún ọ; àwọn ìlú orílẹ̀-èdè aláìláàánú yóò bu ọlá fún ọ.
Isaiah 25:3 in English
Isaiah 25:3 · Berean Standard Bible
Therefore, a strong people will honor You. The cities of ruthless nations will revere You.
Context
1Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run mi;
èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sì
fi ìyìn fún orúkọ rẹ
nítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́
o ti ṣe ohun ńlá,
àwọn ohun tí o ti gbèrò o rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́. 2Ìwọ ti sọ ìlú di àkójọ àlàpà,
ìlú olódi ti di ààtàn,
ìlú olódi fún àwọn àjèjì ni kò sí mọ́;
a kì yóò tún un kọ́ mọ́. 3Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóò
bọ̀wọ̀ fún ọ;
àwọn ìlú orílẹ̀-èdè aláìláàánú
yóò bu ọlá fún ọ. 4Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòṣì
ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njú rẹ̀
ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì
bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru.
Nítorí pé èémí àwọn ìkà
dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri 5àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní aginjù.
O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì,
gẹ́gẹ́ bí òjìji kurukuru ṣe ń dín ooru kù,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.