Isaiah 24:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ, gbogbo àwọn aláríyá sì kérora.
Isaiah 24:7 in English
Isaiah 24:7 · Berean Standard Bible
The new wine dries up, the vine withers. All the merrymakers now groan.
Context
5àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́;
wọ́n ti pa àwọn òfin run
wọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànà
wọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́. 6Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run;
àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn.
Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù,
àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù. 7Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ,
gbogbo àwọn aláríyá sì kérora. 8Àríyá ti ṣaworo ti dákẹ́
ariwo àwọn tí ń ṣàjọyọ̀ ti dáwọ́ dúró
ayọ̀ dùùrù ti dákẹ́ jẹ́ẹ́. 9Kò ṣe é ṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́
ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.