Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

bákan náà ni yóò sì rí fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn, fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀, fún ìyá-ilé àti ọmọbìnrin, fún olùtà àti olùrà, fún ayáni àti atọrọ fún ayánilówó àti onígbèsè.

Isaiah 24:2 in English

Isaiah 24:2 · Berean Standard Bible

people and priest alike, servant and master, maid and mistress, buyer and seller, lender and borrower, creditor and debtor.

Context

1Kíyèsi i, Olúwa yóò sọ ohun gbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayé yóò sì pa á run òun yóò pa ojú u rẹ̀ rẹ́ yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri— 2bákan náà ni yóò sì rí fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn, fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀, fún ìyá-ilé àti ọmọbìnrin, fún olùtà àti olùrà, fún ayáni àti atọrọ fún ayánilówó àti onígbèsè. 3Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátápátá a ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run. Olúwa ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí. 4Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì sá, ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un, àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.