Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì sá, ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un, àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú

Isaiah 24:4 in English

Isaiah 24:4 · Berean Standard Bible

The earth mourns and withers; the world languishes and fades; the exalted of the earth waste away.

Context

2bákan náà ni yóò sì rí fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn, fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀, fún ìyá-ilé àti ọmọbìnrin, fún olùtà àti olùrà, fún ayáni àti atọrọ fún ayánilówó àti onígbèsè. 3Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátápátá a ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run. Olúwa ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí. 4Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì sá, ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un, àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú 5àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́; wọ́n ti pa àwọn òfin run wọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànà wọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́. 6Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run; àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn. Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù, àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.