Isaiah 24:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro, ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì tì pa bámú bámú.
Isaiah 24:12 in English
Isaiah 24:12 · Berean Standard Bible
The city is left in ruins; its gate is reduced to rubble.
Context
10Ìlú tí a run ti dahoro,
ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa. 11Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnì
gbogbo ayọ̀ ọ wọn ti di ìbànújẹ́,
gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé. 12Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro,
ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì tì pa bámú bámú. 13Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayé
àti láàrín àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú,
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi olifi,
tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìn
tí a kórè èso tán. 14Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀;
láti ìwọ̀-oòrùn ni wọn yóò ti polongo
ọláńlá Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.