Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnì gbogbo ayọ̀ ọ wọn ti di ìbànújẹ́, gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé.

Isaiah 24:11 in English

Isaiah 24:11 · Berean Standard Bible

In the streets they cry out for wine. All joy turns to gloom; rejoicing is exiled from the land.

Context

9Kò ṣe é ṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́ ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu. 10Ìlú tí a run ti dahoro, ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa. 11Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnì gbogbo ayọ̀ ọ wọn ti di ìbànújẹ́, gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé. 12Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro, ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì tì pa bámú bámú. 13Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayé àti láàrín àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi olifi, tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìn tí a kórè èso tán.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.