Isaiah 22:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn ẹlẹ́ṣin ni a gbá jọ sí ẹnu-bodè ìlú.
Isaiah 22:7 in English
Isaiah 22:7 · Berean Standard Bible
Your choicest valleys are full of chariots, and horsemen are posted at the gates.
Context
5Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan
tí rúkèrúdò àti rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀
ní àfonífojì ìmọ̀,
ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀
àti sísun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè. 6Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́,
pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin,
Kiri yọ àpáta rẹ̀ síta. 7Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun,
àwọn ẹlẹ́ṣin ni a gbá jọ sí ẹnu-bodè ìlú. 8Gbogbo ààbò Juda ni a ti ká kúrò.
Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náà
sí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú aginjù. 9Ìwọ rí i pé ìlú u Dafidi
ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀,
ìwọ ti tọ́jú omi
sínú adágún ti ìsàlẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.