Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan tí rúkèrúdò àti rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ní àfonífojì ìmọ̀, ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀ àti sísun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè.

Isaiah 22:5 in English

Isaiah 22:5 · Berean Standard Bible

For the Lord GOD of Hosts has set a day of tumult and trampling and confusion in the Valley of Vision— of breaking down the walls and crying to the mountains.

Context

3Gbogbo àwọn olórí i yín ti jùmọ̀ sálọ; a ti kó wọn nígbèkùn láìlo ọfà. Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀, lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀tá ṣì wà lọ́nà jíjìn réré. 4Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi: jẹ́ kí n sọkún kíkorò. Má ṣe gbìyànjú àti tù mí nínú nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.” 5Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan tí rúkèrúdò àti rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ní àfonífojì ìmọ̀, ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀ àti sísun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè. 6Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin, Kiri yọ àpáta rẹ̀ síta. 7Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn ẹlẹ́ṣin ni a gbá jọ sí ẹnu-bodè ìlú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.