Isaiah 21:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gún mọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà, mo sọ ohun tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Israẹli.
Isaiah 21:10 in English
Isaiah 21:10 · Berean Standard Bible
O my people, crushed on the threshing floor, I tell you what I have heard from the LORD of Hosts, the God of Israel.
Context
8Òun sì kígbe pé, kìnnìún kan,
“Láti ọjọ́ dé ọjọ́, olúwa mi, mo dúró lórí ilé ìṣọ́ ní ọ̀sán,
a sì fi mí ìṣọ́ mi ní gbogbo òru. 9Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀ wá yìí nínú kẹ̀kẹ́ ogun
àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin.
Ó sì mú ìdáhùn padà wá:
‘Babeli ti ṣubú, ó ti ṣubú!
Gbogbo àwọn ère òrìṣà rẹ̀
ló fọ́nká sórí ilẹ̀!’ ” 10Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gún mọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà,
mo sọ ohun tí mo ti gbọ́
láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Israẹli. 11Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Dumahi.
Ẹnìkan ké sí mi láti Seiri wá,
“Alóre, kí ló kù nínú òru náà?” 12Alóre náà dáhùn wí pé,
“Òwúrọ̀ súnmọ́ tòsí, àti òru náà pẹ̀lú.
Bí ìwọ yóò bá béèrè, béèrè;
kí o sì tún padà wá.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.