Isaiah 19:1
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Ejibiti. Kíyèsi i, Olúwa gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́ṣin ó sì ń bọ̀ wá sí Ejibiti. Àwọn ère òrìṣà Ejibiti wárìrì níwájú rẹ̀, ọkàn àwọn ará Ejibiti sì ti domi nínú wọn.
Isaiah 19:1 in English
Isaiah 19:1 · Berean Standard Bible
This is the burden against Egypt: Behold, the LORD rides on a swift cloud; He is coming to Egypt. The idols of Egypt will tremble before Him, and the hearts of the Egyptians will melt within them.
Context
1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Ejibiti.
Kíyèsi i, Olúwa gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́ṣin
ó sì ń bọ̀ wá sí Ejibiti.
Àwọn ère òrìṣà Ejibiti wárìrì níwájú rẹ̀,
ọkàn àwọn ará Ejibiti sì ti domi nínú wọn. 2“Èmi yóò rú àwọn ará Ejibiti sókè sí ara wọn
arákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà,
aládùúgbò yóò dìde sí aládùúgbò rẹ̀,
ìlú yóò dìde sí ìlú,
ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba. 3Àwọn ará Ejibiti yóò sọ ìrètí nù,
èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo;
wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀,
àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.