Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Èmi yóò rú àwọn ará Ejibiti sókè sí ara wọn arákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà, aládùúgbò yóò dìde sí aládùúgbò rẹ̀, ìlú yóò dìde sí ìlú, ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba.

Isaiah 19:2 in English

Isaiah 19:2 · Berean Standard Bible

“So I will incite Egyptian against Egyptian; brother will fight against brother, neighbor against neighbor, city against city, and kingdom against kingdom.

Context

1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Ejibiti. Kíyèsi i, Olúwa gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́ṣin ó sì ń bọ̀ wá sí Ejibiti. Àwọn ère òrìṣà Ejibiti wárìrì níwájú rẹ̀, ọkàn àwọn ará Ejibiti sì ti domi nínú wọn. 2“Èmi yóò rú àwọn ará Ejibiti sókè sí ara wọn arákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà, aládùúgbò yóò dìde sí aládùúgbò rẹ̀, ìlú yóò dìde sí ìlú, ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba. 3Àwọn ará Ejibiti yóò sọ ìrètí nù, èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo; wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀, àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀. 4Èmi yóò fi Ejibiti lé agbára àwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́, ọba aláìláàánú ni yóò jẹ ọba lé wọn lórí,” ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.