Isaiah 16:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọkàn mi kérora fún Moabu gẹ́gẹ́ bí i dùùrù, àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Kiri-Hareseti.
Isaiah 16:11 in English
Isaiah 16:11 · Berean Standard Bible
Therefore my heart laments for Moab like a harp, my inmost being for Kir-heres.*
Context
9Nítorí náà mo sọkún, gẹ́gẹ́ bí Jaseri ṣe sọkún,
fún àwọn àjàrà Sibma.
Ìwọ Heṣboni, ìwọ Eleale,
mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú!
Igbe ayọ̀ lórí àwọn èso pípọ́n rẹ
àti lórí ìkórè èyí tí o ti mọ́wọ́ dúró. 10Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò
nínú ọgbà-igi eléso rẹ;
kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí
kígbe nínú ọgbà àjàrà:
ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí,
nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe. 11Ọkàn mi kérora fún Moabu gẹ́gẹ́ bí i dùùrù,
àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Kiri-Hareseti. 12Nígbà tí Moabu farahàn ní ibi gíga rẹ̀,
ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán;
nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúrà
òfo ni ó jásí. 13Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa Moabu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.