Isaiah 13:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbé àsíá sókè ní orí òkè gbẹrẹfu, kígbe sí wọn, pè wọ́n láti wọlé sí ẹnu-ọ̀nà àwọn ọlọ́lá.
Isaiah 13:2 in English
Isaiah 13:2 · Berean Standard Bible
Raise a banner on a barren hilltop; call aloud to them. Wave your hand, that they may enter the gates of the nobles.
Context
1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Babeli èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí. 2Gbé àsíá sókè ní orí òkè gbẹrẹfu,
kígbe sí wọn,
pè wọ́n
láti wọlé sí ẹnu-ọ̀nà àwọn ọlọ́lá. 3Mo ti pàṣẹ fún àwọn ẹni mímọ́ mi,
mo ti pe àwọn jagunjagun mi
láti gbé ìbínú mi jáde
àwọn tí ń yọ̀ nínú ìṣẹ́gun mi. 4Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè,
gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn.
Gbọ́ ìdàrúdàpọ̀ láàrín àwọn ìjọba,
gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè!
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọ
àwọn jagunjagun fún ogun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.