Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti ìkójọpọ̀ wọn kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn. Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn yóò di òkùnkùn àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn.

Isaiah 13:10 in English

Isaiah 13:10 · Berean Standard Bible

For the stars of heaven and their constellations will not give their light. The rising sun will be darkened, and the moon will not give its light.

Context

8Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú, ìrora àti ìpayínkeke yóò dìwọ́n mú, wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí. Ẹnìkínní yóò wo ẹnìkejì rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà ojú wọn á sì gbinájẹ. 9Kíyèsi i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínú àti ìrunú gbígbóná— láti sọ ilẹ̀ náà dahoro, àti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run. 10Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti ìkójọpọ̀ wọn kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn. Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn yóò di òkùnkùn àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn. 11Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀, àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéraga èmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀. 12Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọn ju ojúlówó wúrà lọ, yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ofiri lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.