Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ó sọ pé: “ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ mi ni mo fi ṣe èyí àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye. Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀-èdè kúrò, mo sì ti kó ìṣúra wọn. Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.

Isaiah 10:13 in English

Isaiah 10:13 · Berean Standard Bible

For he says: ‘By the strength of my hand I have done this, and by my wisdom, for I am clever. I have removed the boundaries of nations and plundered their treasures; like a mighty one I subdued their rulers.

Context

11Èmi kì yóò a bá Jerusalẹmu wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ” Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Samaria àti àwọn ère rẹ̀? 12Nígbà tí Olúwa ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Sioni àti Jerusalẹmu, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Asiria nítorí gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojú rẹ̀. 13Nítorí ó sọ pé: “ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ mi ni mo fi ṣe èyí àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye. Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀-èdè kúrò, mo sì ti kó ìṣúra wọn. Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn. 14Bí ènìyàn ti í tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Bí ènìyàn ti í kó ẹyin tí a kọ̀sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀-èdè kò sí èyí tí ó fi apá lu apá, tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ” 15Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í, tàbí kí ayùn fọ́nnu sí ẹni tí ó ń lò ó? Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè, tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.