Isaiah 1:22
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fàdákà rẹ ti di ìpẹ́pẹ́, ààyò wáìnì rẹ la ti bu omi là.
Isaiah 1:22 in English
Isaiah 1:22 · Berean Standard Bible
Your silver has become dross; your fine wine is diluted with water.
Context
20Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀,
idà ni a ó fi pa yín run.”
Nítorí ẹnu Olúwa la ti sọ ọ́. 21Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè!
Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí,
òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí,
ṣùgbọ́n báyìí àwọn apànìyàn! 22Fàdákà rẹ ti di ìpẹ́pẹ́,
ààyò wáìnì rẹ la ti bu omi là. 23Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín,
akẹgbẹ́ àwọn olè,
gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀
wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri.
Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,
ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn. 24Nítorí náà ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
alágbára kan ṣoṣo tí Israẹli sọ wí pé:
“Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá mi
n ó sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.