Hosea 9:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ilẹ̀ ìpakà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀.
Hosea 9:2 in English
Hosea 9:2 · Berean Standard Bible
The threshing floor and winepress will not feed them, and the new wine will fail them.
Context
1Má ṣe yọ̀, ìwọ Israẹli;
má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.
Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìṣòótọ́ si Ọlọ́run yín.
Ẹ fẹ́ràn láti gba owó iṣẹ́ àgbèrè
ní gbogbo ilẹ̀ ìpakà. 2Àwọn ilẹ̀ ìpakà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ
wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀. 3Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé Olúwa
Efraimu yóò padà sí Ejibiti,
yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ́ ní Asiria. 4Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa.
Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn.
Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀.
Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́.
Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnra wọn
kò ní wá sí orí tẹmpili Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.