Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀.

Hosea 6:7 in English

Hosea 6:7 · Berean Standard Bible

But they, like Adam, have transgressed * the covenant; there they were unfaithful to Me.

Context

5Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín. 6Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ; àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ. 7Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀. 8Gileadi jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́. 9Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùba de àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀; tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣekemu, tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.