Hosea 6:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín.
Hosea 6:5 in English
Hosea 6:5 · Berean Standard Bible
Therefore I have hewn them by the prophets; I have slain them by the words of My mouth, and My judgments go forth like lightning.
Context
3Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa;
ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n.
Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,
yóò jáde;
yóò tọ̀ wá wá bí òjò,
bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.” 4“Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu?
Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda?
Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀
bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá. 5Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì,
Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi,
ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín. 6Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;
àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ. 7Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú
wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.