Hosea 6:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀.
Hosea 6:2 in English
Hosea 6:2 · Berean Standard Bible
After two days He will revive us; on the third day He will raise us up, that we may live in His presence.
Context
1“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa
ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá
Ó ti pa wá lára
ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa. 2Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí
ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò
kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀. 3Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa;
ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n.
Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,
yóò jáde;
yóò tọ̀ wá wá bí òjò,
bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.” 4“Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu?
Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda?
Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀
bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.