Hosea 5:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
mo mọ ohun gbogbo nípa Efraimu Israẹli kò sì pamọ́ fún mi Efraimu, ní báyìí ó ti ṣe àgbèrè Israẹli sì ti díbàjẹ́.
Hosea 5:3 in English
Hosea 5:3 · Berean Standard Bible
I know all about Ephraim,* and Israel is not hidden from Me. For now, O Ephraim, you have turned to prostitution; Israel is defiled.
Context
1“Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà!
Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Israẹli!
Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba!
Ìdájọ́ yìí kàn yín.
Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mispa
àwọ̀n ti a nà sílẹ̀ lórí Tabori. 2Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn
gbogbo wọn ni èmi ó bá wí, 3mo mọ ohun gbogbo nípa Efraimu
Israẹli kò sì pamọ́ fún mi
Efraimu, ní báyìí ó ti ṣe àgbèrè
Israẹli sì ti díbàjẹ́. 4“Ìṣe wọn kò gbà wọ́n láààyè
láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn.
Ẹ̀mí àgbèrè wà ni ọkàn wọn,
wọn kò sì mọ Olúwa. 5Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí lé wọn;
àwọn ọmọ Israẹli, àti Efraimu pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Juda náà sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.