Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Israẹli, ìdájọ́ yìí wà fún un yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí Juda di ẹlẹ́bi. “Ẹ má ṣe lọ sí Gilgali. Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Beti-Afeni ẹ má sì búra pé, ‘Bí Olúwa ti wà láààyè nítòótọ́!’

Hosea 4:15 in English

Hosea 4:15 · Berean Standard Bible

Though you prostitute yourself, O Israel, may Judah avoid such guilt! Do not journey to Gilgal, do not go up to Beth-aven,* and do not swear on oath, ‘As surely as the LORD lives!’

Context

13Wọ́n ń rú ẹbọ lórí àwọn òkè ńlá, wọ́n sì ń sun ọrẹ tùràrí lórí àwọn òkè kékeré, lábẹ́ igi óákù, àti igi Poplari àti igi ẹlimuati onírúurú igi tí ìbòjú rẹ̀ dára. Nítorí náà àwọn ọmọbìnrin yín yóò ṣe àgbèrè àti àwọn àfẹ́sọ́nà yín yóò ṣe àgbèrè. 14“Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yín ní yà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè tàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín, nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè nítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́. Wọ́n sì ń rú ẹbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ojúbọ òrìṣà. Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun! 15“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Israẹli, ìdájọ́ yìí wà fún un yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí Juda di ẹlẹ́bi. “Ẹ má ṣe lọ sí Gilgali. Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Beti-Afeni ẹ má sì búra pé, ‘Bí Olúwa ti wà láààyè nítòótọ́!’ 16Àwọn ọmọ Israẹli ṣe agídí bí alágídí ọmọ màlúù. Báwo wá ni Olúwa ṣe fẹ́ bọ́ wọn bí àgùntàn ní pápá oko tútù? 17Efraimu ti darapọ̀ mọ́ òrìṣà, ẹ fi sílẹ̀!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.