Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi o dàbí ìrì sí Israẹli, wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì. Bi kedari ti Lebanoni yóò si ta gbòǹgbò.

Hosea 14:5 in English

Hosea 14:5 · Berean Standard Bible

I will be like the dew to Israel; he will blossom like the lily and take root like the cedars of Lebanon.

Context

3Asiria kò le gbà wá là; a kò ní í gorí ẹṣin ogun. A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé, ‘Àwọn ni òrìṣà wa’ sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe; nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn aláìní baba tí ń rí àánú.” 4“Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn, Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn. 5Èmi o dàbí ìrì sí Israẹli, wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì. Bi kedari ti Lebanoni yóò si ta gbòǹgbò. 6Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà, dídán ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi olifi. Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi kedari ti Lebanoni. 7Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀. Yóò rúwé bi ọkà. Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà, òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lebanoni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.