Hosea 14:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà, dídán ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi olifi. Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi kedari ti Lebanoni.
Hosea 14:6 in English
Hosea 14:6 · Berean Standard Bible
His shoots will sprout, and his splendor will be like the olive tree, his fragrance like the cedars of Lebanon.
Context
4“Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn,
Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́,
nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn. 5Èmi o dàbí ìrì sí Israẹli,
wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì.
Bi kedari ti Lebanoni yóò si ta gbòǹgbò. 6Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà,
dídán ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi olifi.
Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi kedari ti Lebanoni. 7Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀.
Yóò rúwé bi ọkà.
Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà,
òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lebanoni. 8Ìwọ Efraimu, kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà?
Èmi ó dá a lóhùn, èmi ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ.
Mo dàbí igi junifa tó ń fi gbogbo ìgbà tutù,
èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.