Hosea 14:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ gba ọ̀rọ̀ Olúwa gbọ́, kí ẹ sì yípadà sí Olúwa. Ẹ sọ fún un pé, “Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá kí o sì fi oore-ọ̀fẹ́ gbà wá, kí àwa kí ó lè fi ètè wa sán an fún ọ
Hosea 14:2 in English
Hosea 14:2 · Berean Standard Bible
Bring your confessions and return to the LORD. Say to Him: “Take away all our iniquity and receive us graciously, that we may present the fruit of our lips.*
Context
1Yípadà ìwọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ! 2Ẹ gba ọ̀rọ̀ Olúwa gbọ́,
kí ẹ sì yípadà sí Olúwa.
Ẹ sọ fún un pé,
“Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá
kí o sì fi oore-ọ̀fẹ́ gbà wá,
kí àwa kí ó lè fi ètè wa sán an fún ọ 3Asiria kò le gbà wá là;
a kò ní í gorí ẹṣin ogun.
A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé, ‘Àwọn ni òrìṣà wa’
sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe;
nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn aláìní baba tí ń rí àánú.” 4“Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn,
Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́,
nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.