Heberu 10:7
Hebrews 10:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Kíyèsi i (nínú ìwé kíká ni a gbé kọ ọ́ nípa ti èmi) mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’ ”
Hebrews 10:7 in English
Hebrews 10:7 · Berean Standard Bible
Then I said, ‘Here I am, it is written about Me in the scroll: I have come to do Your will, O God.’”*
Context
5Nítorí náà nígbà tí Kristi wá sí ayé, ó wí pé,
“Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ,
ṣùgbọ́n ara ni ìwọ ti pèsè fún mi, 6ẹbọ sísun àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni
ìwọ kò ní inú dídùn sí. 7Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Kíyèsi i (nínú ìwé kíká ni a gbé kọ ọ́ nípa ti èmi)
mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’ ” 8Nígbà tí o wí ni ìṣáájú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin). 9Nígbà náà ni ó wí pé, “Kíyèsi i, mo de láti ṣe ìfẹ́ rẹ Ọlọ́run.” Ó mú ti ìṣáájú kúrò, kí a lè fi ìdí èkejì múlẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.