Heberu 10:8
Hebrews 10:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí o wí ni ìṣáájú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin).
Hebrews 10:8 in English
Hebrews 10:8 · Berean Standard Bible
In the passage above He says, “Sacrifices and offerings, burnt offerings and sin offerings You did not desire, nor did You delight in them” (although they are offered according to the law).
Context
6ẹbọ sísun àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni
ìwọ kò ní inú dídùn sí. 7Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Kíyèsi i (nínú ìwé kíká ni a gbé kọ ọ́ nípa ti èmi)
mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’ ” 8Nígbà tí o wí ni ìṣáájú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin). 9Nígbà náà ni ó wí pé, “Kíyèsi i, mo de láti ṣe ìfẹ́ rẹ Ọlọ́run.” Ó mú ti ìṣáájú kúrò, kí a lè fi ìdí èkejì múlẹ̀. 10Nípa ìfẹ́ náà ni a ti sọ wá di mímọ́ nípa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.