Native Bible

Genesis 9:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítòótọ́ ẹ̀jẹ̀ yín, àní ẹ̀mí yín, ni èmi yóò sì béèrè; lọ́wọ́ gbogbo ẹranko ni èmí yóò béèrè rẹ̀, àti lọ́wọ́ ènìyàn, lọ́wọ́ arákùnrin olúkúlùkù ènìyàn ni èmi yóò béèrè ẹ̀mí ènìyàn.

Genesis 9:5 in English

Genesis 9:5 · Berean Standard Bible

And surely I will require the life of any man or beast by whose hand your lifeblood is shed. I will demand an accounting from anyone who takes the life of his fellow man:

Context

3Gbogbo ohun tó wà láààyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín, bí mo ṣe fi ewéko fún un yín náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín. 4“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 5Nítòótọ́ ẹ̀jẹ̀ yín, àní ẹ̀mí yín, ni èmi yóò sì béèrè; lọ́wọ́ gbogbo ẹranko ni èmí yóò béèrè rẹ̀, àti lọ́wọ́ ènìyàn, lọ́wọ́ arákùnrin olúkúlùkù ènìyàn ni èmi yóò béèrè ẹ̀mí ènìyàn. 6“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀, láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó gbà ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Nítorí ní àwòrán Ọlọ́run ni Ọlọ́run dá ènìyàn. 7Ṣùgbọ́n ní tiyín, ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ máa gbá yìn lórí ilẹ̀, kí ẹ sì pọ̀ sí i lórí rẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.