Native Bible

Genesis 9:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ohun tó wà láààyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín, bí mo ṣe fi ewéko fún un yín náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín.

Genesis 9:3 in English

Genesis 9:3 · Berean Standard Bible

Everything that lives and moves will be food for you; just as I gave you the green plants, I now give you all things.

Context

1Ọlọ́run sì súre fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ wí pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì pọ̀ ní iye, kí ẹ sì kún ayé. 2Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́. 3Gbogbo ohun tó wà láààyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín, bí mo ṣe fi ewéko fún un yín náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín. 4“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 5Nítòótọ́ ẹ̀jẹ̀ yín, àní ẹ̀mí yín, ni èmi yóò sì béèrè; lọ́wọ́ gbogbo ẹranko ni èmí yóò béèrè rẹ̀, àti lọ́wọ́ ènìyàn, lọ́wọ́ arákùnrin olúkúlùkù ènìyàn ni èmi yóò béèrè ẹ̀mí ènìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.