Gẹnẹsisi 9:25
Genesis 9:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó wí pé, “Ègún ni fún Kenaani. Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máa ṣe fún àwọn arákùnrin rẹ̀.”
Genesis 9:25 in English
Genesis 9:25 · Berean Standard Bible
he said, “Cursed be Canaan! A servant of servants shall he be to his brothers.”
Context
23Ṣùgbọ́n Ṣemu àti Jafeti mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòhò baba wọn. Wọ́n kọjú sẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòhò baba wọn. 24Nígbà tí Noa kúrò ní ojú ọtí, tí ó sì mọ ohun tí ọmọ rẹ̀ kékeré ṣe sí i. 25Ó wí pé,
“Ègún ni fún Kenaani.
Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máa ṣe
fún àwọn arákùnrin rẹ̀.” 26Ó sì tún wí pé,
“Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Ṣemu
Kenaani yóò máa ṣe ẹrú fún Ṣemu. 27Ọlọ́run yóò mú Jafeti gbilẹ̀,
Jafeti yóò máa gbé ní àgọ́ Ṣemu
Kenaani yóò sì jẹ́ ẹrú fún un.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.