Gẹnẹsisi 6:15
Genesis 6:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà: Gígùn rẹ̀ ní òró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún (300) ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́.
Genesis 6:15 in English
Genesis 6:15 · Berean Standard Bible
And this is how you are to build it: The ark is to be 300 cubits long, 50 cubits wide, and 30 cubits high.*
Context
13Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èmi yóò pa gbogbo ènìyàn run, nítorí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nípasẹ̀ wọn. Èmi yóò pa wọ́n run àti ayé pẹ̀lú. 14Nítorí náà fi igi ọ̀mọ̀ kan ọkọ̀, kí o sì yọ yàrá sí inú rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ tinú-tẹ̀yìn. 15Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà: Gígùn rẹ̀ ní òró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún (300) ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́. 16Ṣe òrùlé sí orí ọkọ̀ náà ní ìgbọ̀nwọ́ kan, sì ṣe ọkọ̀ náà ní alájà mẹ́ta, ipá kan ní ìsàlẹ̀, ọ̀kan ní àárín àti ọ̀kan tí ó kù ní òkè, ẹ̀gbẹ́ ni kí ó ṣe ẹnu-ọ̀nà ọkọ̀ náà sí. 17Èmi yóò mú ìkún omi wá sí ayé láti pa gbogbo ohun ẹlẹ́mìí run lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè ní inú. Gbogbo ohun tí ó wà nínú ayé yóò parun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.