Gẹnẹsisi 6:13
Genesis 6:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èmi yóò pa gbogbo ènìyàn run, nítorí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nípasẹ̀ wọn. Èmi yóò pa wọ́n run àti ayé pẹ̀lú.
Genesis 6:13 in English
Genesis 6:13 · Berean Standard Bible
Then God said to Noah, “The end of all living creatures has come before Me, because through them the earth is full of violence. Now behold, I will destroy both them and the earth.
Context
11Ayé sì kún fún ìbàjẹ́ gidigidi ní ojú Ọlọ́run, ó sì kún fún ìwà ipá pẹ̀lú. 12Ọlọ́run sì rí bí ayé ti bàjẹ́ tó, nítorí àwọn ènìyàn inú ayé ti bá ara wọn jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà wọn. 13Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èmi yóò pa gbogbo ènìyàn run, nítorí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nípasẹ̀ wọn. Èmi yóò pa wọ́n run àti ayé pẹ̀lú. 14Nítorí náà fi igi ọ̀mọ̀ kan ọkọ̀, kí o sì yọ yàrá sí inú rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ tinú-tẹ̀yìn. 15Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà: Gígùn rẹ̀ ní òró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún (300) ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.