Native Bible

Genesis 50:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kẹ̀kẹ́-ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin pẹ̀lú gòkè lọ. Àìmoye ènìyàn ni ó lọ.

Genesis 50:9 in English

Genesis 50:9 · Berean Standard Bible

Chariots and horsemen alike went up with him, and it was an exceedingly large procession.

Context

7Báyìí ni Josẹfu gòkè lọ láti sìnkú baba rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjòyè Farao ni ó sìn ín lọ—àwọn àgbàgbà ilé rẹ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà ilẹ̀ Ejibiti. 8Yàtọ̀ fún gbogbo àwọn ará ilé Josẹfu àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn tí ó jẹ́ ilé baba rẹ̀, àwọn ọmọ wọn nìkan àti agbo ẹran pẹ̀lú agbo màlúù ni ó sẹ́ kù ní Goṣeni. 9Kẹ̀kẹ́-ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin pẹ̀lú gòkè lọ. Àìmoye ènìyàn ni ó lọ. 10Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ ìpakà Atadi, ní ẹ̀bá Jordani, wọn pohùnréré ẹkún, níbẹ̀ ni Josẹfu sì tún dúró ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ méje. 11Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí ń gbé níbẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ náà ni ilẹ̀ ìpakà Atadi, wọ́n wí pé, “Ọ̀fọ̀ ńlá ni àwọn ará Ejibiti ń ṣe yìí.” Ìdí èyí ni a fi ń pe ibẹ̀ ní Abeli-Misraimu.* Kò sì jìnnà sí Jordani.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.