Gẹnẹsisi 50:10
Genesis 50:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ ìpakà Atadi, ní ẹ̀bá Jordani, wọn pohùnréré ẹkún, níbẹ̀ ni Josẹfu sì tún dúró ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ méje.
Genesis 50:10 in English
Genesis 50:10 · Berean Standard Bible
When they reached the threshing floor of Atad, which is across the Jordan, they lamented and wailed loudly, and Joseph mourned for his father seven days.
Context
8Yàtọ̀ fún gbogbo àwọn ará ilé Josẹfu àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn tí ó jẹ́ ilé baba rẹ̀, àwọn ọmọ wọn nìkan àti agbo ẹran pẹ̀lú agbo màlúù ni ó sẹ́ kù ní Goṣeni. 9Kẹ̀kẹ́-ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin pẹ̀lú gòkè lọ. Àìmoye ènìyàn ni ó lọ. 10Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ ìpakà Atadi, ní ẹ̀bá Jordani, wọn pohùnréré ẹkún, níbẹ̀ ni Josẹfu sì tún dúró ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ méje. 11Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí ń gbé níbẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ náà ni ilẹ̀ ìpakà Atadi, wọ́n wí pé, “Ọ̀fọ̀ ńlá ni àwọn ará Ejibiti ń ṣe yìí.” Ìdí èyí ni a fi ń pe ibẹ̀ ní Abeli-Misraimu.* Kò sì jìnnà sí Jordani. 12Báyìí ni àwọn ọmọ Jakọbu ṣe ohun tí baba wọn pàṣẹ fún wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.