Gẹnẹsisi 5:18
Genesis 5:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Jaredi pé ọmọ ọgọ́jọ ọdún ó lé méjì ni ó bí Enoku.
Genesis 5:18 in English
Genesis 5:18 · Berean Standard Bible
When Jared was 162 years old, he became the father of Enoch.
Context
16Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 17Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó dín márùn-ún (895), ó sì kú. 18Nígbà tí Jaredi pé ọmọ ọgọ́jọ ọdún ó lé méjì ni ó bí Enoku. 19Lẹ́yìn èyí, Jaredi wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin (800) ọdún Enoku sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 20Àpapọ̀ ọdún Jaredi sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún dín méjìdínlógójì (962), ó sì kú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.