Gẹnẹsisi 48:20
Genesis 48:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó súre fún wọn lọ́jọ́ náà pé, “Ní orúkọ yín ni Israẹli yóò máa súre yìí pé, ‘Kí Ọlọ́run ṣe ọ́ bí i ti Efraimu àti Manase.’ ” Ó sì gbé Efraimu gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n sí Manase.
Genesis 48:20 in English
Genesis 48:20 · Berean Standard Bible
So that day Jacob blessed them and said: “By you shall Israel pronounce this blessing: ‘May God make you like Ephraim and Manasseh.’” So he put Ephraim before Manasseh.
Context
18Josẹfu wí fun pé, “Rárá, baba mi, èyí ni àkọ́bí, orí rẹ̀ ni kí ìwọ kí o gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé.” 19Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà, ó wí pé, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà yóò di orílẹ̀-èdè, òun náà yóò sì di ńlá. Ṣùgbọ́n àbúrò rẹ̀ yóò di ẹni ńlá jù ú lọ, irú-ọmọ rẹ yóò sì di ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.” 20Ó súre fún wọn lọ́jọ́ náà pé,
“Ní orúkọ yín ni Israẹli yóò máa súre yìí pé,
‘Kí Ọlọ́run ṣe ọ́ bí i ti Efraimu àti Manase.’ ”
Ó sì gbé Efraimu gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n sí Manase. 21Nígbà náà ni Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Ọjọ́ ikú mi súnmọ́ etílé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò wà pẹ̀lú yín, yóò sì mú un yín padà sí ilẹ̀ àwọn baba yín. 22Pẹ̀lúpẹ̀lú èmi yóò fún ọ ní ìpín kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ. Ilẹ̀ tí mo fi idà àti ọ̀kọ̀ mi gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori.”
48.3 El-Ṣaddai tí ó túmọ̀ sí, Ọlọ́run Olódùmarè
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.