Native Bible

Genesis 45:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báyìí ni wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wá sí ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani.

Genesis 45:25 in English

Genesis 45:25 · Berean Standard Bible

So the brothers went up out of Egypt and came to their father Jacob in the land of Canaan.

Context

23Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó ránṣẹ́ sí baba rẹ̀: kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru àwọn ohun mèremère ilẹ̀ Ejibiti àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru ọkà àti oríṣìíríṣìí oúnjẹ. 24Nígbà náà ni ó rán àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, bí wọ́n ṣe ń pínyà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jà ní ọ̀nà o!” 25Báyìí ni wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wá sí ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani. 26Wọn wí fún un pé, “Josẹfu ṣì wà láààyè! Kódà òun ni alákòóso ilẹ̀ Ejibiti.” Ẹnu ya Jakọbu, kò sì gbà wọ́n gbọ́. 27Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sọ ohun gbogbo tí Josẹfu ti sọ fún wọn fún un tí ó sì rí kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Josẹfu fi ránṣẹ́ láti gbé e padà wá, iyè Jakọbu, baba wọn sọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.