Gẹnẹsisi 43:26
Genesis 43:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Josẹfu dé sí ilé, wọ́n kó àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n ti mú wá fún un, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀.
Genesis 43:26 in English
Genesis 43:26 · Berean Standard Bible
When Joseph came home, they presented him with the gifts they had brought, and they bowed to the ground before him.
Context
24Ìránṣẹ́ náà mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Josẹfu, ó fún wọn ní omi láti fi wẹ ẹsẹ̀ wọn nu, ó sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn lóúnjẹ pẹ̀lú. 25Wọ́n pèsè ẹ̀bùn wọn sílẹ̀ fún Josẹfu di ọ̀sán nígbà tí yóò dé, nítorí wọ́n ti gbọ́ pé ibẹ̀ ni àwọn yóò ti jẹun ọ̀sán. 26Nígbà tí Josẹfu dé sí ilé, wọ́n kó àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n ti mú wá fún un, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 27Ó béèrè àlàáfíà wọn, ó sì wí pé, “Ṣé àlàáfíà ni baba yín wà, baba arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣé ó sì wà láààyè?” 28Wọ́n dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ, baba wa sì wà láààyè, àlàáfíà sì ni ó wà pẹ̀lú.” Wọn sì tẹríba láti bọ̀wọ̀ fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.