Native Bible

Genesis 43:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó béèrè àlàáfíà wọn, ó sì wí pé, “Ṣé àlàáfíà ni baba yín wà, baba arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣé ó sì wà láààyè?”

Genesis 43:27 in English

Genesis 43:27 · Berean Standard Bible

He asked if they were well, and then he asked, “How is your elderly father you told me about? Is he still alive?”

Context

25Wọ́n pèsè ẹ̀bùn wọn sílẹ̀ fún Josẹfu di ọ̀sán nígbà tí yóò dé, nítorí wọ́n ti gbọ́ pé ibẹ̀ ni àwọn yóò ti jẹun ọ̀sán. 26Nígbà tí Josẹfu dé sí ilé, wọ́n kó àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n ti mú wá fún un, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 27Ó béèrè àlàáfíà wọn, ó sì wí pé, “Ṣé àlàáfíà ni baba yín wà, baba arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣé ó sì wà láààyè?” 28Wọ́n dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ, baba wa sì wà láààyè, àlàáfíà sì ni ó wà pẹ̀lú.” Wọn sì tẹríba láti bọ̀wọ̀ fún un. 29Bí ó ti wò yíká tí ó sì rí Benjamini àbúrò rẹ̀, tí í ṣe ọmọ ìyá rẹ̀ gan an. Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣe àbúrò yín tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn tí ẹ sọ fún mi nípa rẹ̀ nìyìí?” Ó sì tún wí pe, “Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún ọ, ọmọ mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.