Native Bible

Genesis 4:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lameki wí fún àwọn aya rẹ̀, “Adah àti Silla, ẹ tẹ́tí sí mi; ẹ̀yin aya Lameki, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára.

Genesis 4:23 in English

Genesis 4:23 · Berean Standard Bible

Then Lamech said to his wives: “Adah and Zillah, hear my voice; wives of Lamech, listen to my speech. For I have slain a man for wounding me, a young man for striking me.

Context

21Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè. 22Silla náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Kaini, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin Tubali-Kaini ni Naama. 23Lameki wí fún àwọn aya rẹ̀, “Adah àti Silla, ẹ tẹ́tí sí mi; ẹ̀yin aya Lameki, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára. 24Bí a ó bá gbẹ̀san Kaini ní ìgbà méje, ǹjẹ́ kí a gba ti Lameki nígbà mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77).” 25Adamu sì tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Seti, tí ó túmọ̀ sí pé, “Ọlọ́run fún mi ní ọmọkùnrin mìíràn ní ipò Abeli tí Kaini pa.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.