Gẹnẹsisi 4:22
Genesis 4:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Silla náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Kaini, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin Tubali-Kaini ni Naama.
Genesis 4:22 in English
Genesis 4:22 · Berean Standard Bible
And Zillah gave birth to Tubal-cain, a forger of every implement of bronze and iron. And the sister of Tubal-cain was Naamah.
Context
20Adah sì bí Jabali, òun ni baba irú àwọn tí ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran ọ̀sìn. 21Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè. 22Silla náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Kaini, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin Tubali-Kaini ni Naama. 23Lameki wí fún àwọn aya rẹ̀,
“Adah àti Silla, ẹ tẹ́tí sí mi;
ẹ̀yin aya Lameki, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.
Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí,
ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára. 24Bí a ó bá gbẹ̀san Kaini ní ìgbà méje,
ǹjẹ́ kí a gba ti Lameki nígbà mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77).”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.