Native Bible

Genesis 39:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún àwọn ará Ejibiti nítorí Josẹfu. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Potifari ní, nílé àti lóko.

Genesis 39:5 in English

Genesis 39:5 · Berean Standard Bible

From the time that he put Joseph in charge of his household and all he owned, the LORD blessed the Egyptian’s household on account of him. The LORD’s blessing was on everything he owned, both in his house and in his field.

Context

3Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé. 4Josẹfu sì rí ojúrere Potifari, ó sì di aṣojú rẹ̀, Potifari fi Josẹfu ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. 5Láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún àwọn ará Ejibiti nítorí Josẹfu. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Potifari ní, nílé àti lóko. 6Ó sì fi Josẹfu ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu ṣe àkóso ilé e rẹ̀. Josẹfu sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀, 7lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Josẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.