Native Bible

Genesis 39:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Josẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!”

Genesis 39:7 in English

Genesis 39:7 · Berean Standard Bible

and after some time his master’s wife cast her eyes upon Joseph and said, “Sleep with me.”

Context

5Láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún àwọn ará Ejibiti nítorí Josẹfu. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Potifari ní, nílé àti lóko. 6Ó sì fi Josẹfu ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu ṣe àkóso ilé e rẹ̀. Josẹfu sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀, 7lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Josẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” 8Ṣùgbọ́n Josẹfu kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́. 9Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.