Gẹnẹsisi 37:21
Genesis 37:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Reubeni gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn, ó sì wí pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ẹ̀mí rẹ̀,
Genesis 37:21 in English
Genesis 37:21 · Berean Standard Bible
When Reuben heard this, he tried to rescue Joseph from their hands. “Let us not take his life,” he said.
Context
19“Alálàá ni ń bọ̀ yìí,” ni wọ́n ń wí fún ara wọn. 20“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á. Kí a sì ju òkú rẹ̀ sínú kòtò, a ó sì wí pé, ẹranko búburú ni ó pa á, kí a máa wo ọ̀nà tí àlá rẹ̀ yóò gbà ṣẹ.” 21Nígbà tí Reubeni gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn, ó sì wí pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ẹ̀mí rẹ̀, 22ẹ má ṣe jẹ́ kí a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ má ṣe fọwọ́ kàn án, ẹ kúkú jù ú sínú kòtò láààyè nínú aginjù níbí.” Reubeni sọ èyí, kí ó ba à le gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, kí ó sì dá a padà lọ fún baba rẹ̀. 23Nítorí náà, nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀—Ẹ̀wù ọlọ́nà, aláràbarà tí ó wọ̀—
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.