Gẹnẹsisi 33:3
Genesis 33:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jakọbu fúnra rẹ̀ wa lọ síwájú pátápátá, ó sì tẹríba ní ìgbà méje bí ó ti ń súnmọ́ Esau, arákùnrin rẹ̀.
Genesis 33:3 in English
Genesis 33:3 · Berean Standard Bible
But Jacob himself went on ahead and bowed to the ground seven times as he approached his brother.
Context
1Jakọbu sì gbójú sókè, ó sì rí Esau àti irinwó (400) ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀, ó sì pín àwọn ọmọ fún Lea, Rakeli àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì. 2Ó sì ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn síwájú, Lea àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọ̀wọ́ kejì tí ó tẹ̀lé wọn, Rakeli àti Josẹfu sì wà lẹ́yìn pátápátá. 3Jakọbu fúnra rẹ̀ wa lọ síwájú pátápátá, ó sì tẹríba ní ìgbà méje bí ó ti ń súnmọ́ Esau, arákùnrin rẹ̀. 4Ṣùgbọ́n Esau sáré pàdé Jakọbu, ó sì dì mọ́ ọn, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì fẹnukò ó lẹ́nu. Àwọn méjèèjì sì sọkún. 5Nígbà tí Esau sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ Jakọbu, ó béèrè lọ́wọ́ Jakọbu pé, “Ti ta ni àwọn wọ̀nyí?”
Jakọbu sì fèsì wí pé, “Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.