Gẹnẹsisi 33:2
Genesis 33:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn síwájú, Lea àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọ̀wọ́ kejì tí ó tẹ̀lé wọn, Rakeli àti Josẹfu sì wà lẹ́yìn pátápátá.
Genesis 33:2 in English
Genesis 33:2 · Berean Standard Bible
He put the maidservants and their children in front, Leah and her children next, and Rachel and Joseph at the rear.
Context
1Jakọbu sì gbójú sókè, ó sì rí Esau àti irinwó (400) ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀, ó sì pín àwọn ọmọ fún Lea, Rakeli àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì. 2Ó sì ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn síwájú, Lea àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọ̀wọ́ kejì tí ó tẹ̀lé wọn, Rakeli àti Josẹfu sì wà lẹ́yìn pátápátá. 3Jakọbu fúnra rẹ̀ wa lọ síwájú pátápátá, ó sì tẹríba ní ìgbà méje bí ó ti ń súnmọ́ Esau, arákùnrin rẹ̀. 4Ṣùgbọ́n Esau sáré pàdé Jakọbu, ó sì dì mọ́ ọn, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì fẹnukò ó lẹ́nu. Àwọn méjèèjì sì sọkún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.