Native Bible

Genesis 31:49 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó tún pè é ni Mispa nítorí, ó wí pé, “Kí Olúwa kí ó máa ṣọ́ èmi àti ìwọ nígbà tí a bá yà kúrò lọ́dọ̀ ara wa tán.

Genesis 31:49 in English

Genesis 31:49 · Berean Standard Bible

It was also called Mizpah,* because Laban said, “May the LORD keep watch between you and me when we are absent from each other.

Context

47Labani sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jegari-Sahaduta, ṣùgbọ́n Jakọbu pè é ni Galeedi. 48Labani sì wí pé, “Òkìtì yìí jẹ́ ẹ̀rí láàrín èmi àti ìwọ ní òní.” Ìdí nìyí tí a fi pe orúkọ rẹ̀ ni Galeedi. 49Ó tún pè é ni Mispa nítorí, ó wí pé, “Kí Olúwa kí ó máa ṣọ́ èmi àti ìwọ nígbà tí a bá yà kúrò lọ́dọ̀ ara wa tán. 50Bí o bá fìyà jẹ àwọn ọmọbìnrin mi, tàbí tí o fẹ́ aya mìíràn yàtọ̀ sí wọn, rántí pé, Ọlọ́run ń bẹ láàrín wa bí ẹlẹ́rìí bí ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ sí.” 51Labani tún sọ síwájú fún Jakọbu pé, “Òkìtì àti ọ̀wọ̀n tí mo gbé kalẹ̀ láàrín èmi àti ìwọ yìí,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.