Native Bible

Genesis 31:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nísinsin yìí, ìwọ ti lọ nítorí ìwọ fẹ́ láti padà lọ sí ilé baba rẹ, ṣùgbọ́n èéṣe tí ìwọ fi jí àwọn òrìṣà mi?”

Genesis 31:30 in English

Genesis 31:30 · Berean Standard Bible

Now you have gone off because you long for your father’s house. But why have you stolen my gods?”

Context

28Ìwọ kò tilẹ̀ jẹ́ kí èmi fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ mi lẹ́nu, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mi pé ó dìgbà? Ìwọ ṣiwèrè ní ohun tí ìwọ ṣe yìí. 29Mo ní agbára láti ṣe ọ ni ibi, ṣùgbọ́n ní òru àná, Ọlọ́run baba rẹ sọ fún mi pé, kí èmi ṣọ́ra, kí èmi má ṣe sọ ohun kan fún Jakọbu, ìbá à ṣe rere tàbí búburú. 30Nísinsin yìí, ìwọ ti lọ nítorí ìwọ fẹ́ láti padà lọ sí ilé baba rẹ, ṣùgbọ́n èéṣe tí ìwọ fi jí àwọn òrìṣà mi?” 31Jakọbu dá Labani lóhùn pé, “Ẹ̀rù ni ó bà mi nítorí, mo rò pé ìwọ le fi tipátipá gba àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ́wọ́ mi. 32Ṣùgbọ́n bí o bá ri ẹnikẹ́ni pẹ̀lú ère rẹ, kí ẹni náà di òkú. Ó tún wí pé, níwájú gbogbo ìbátan wa báyìí, wò ó fúnra rẹ̀, bí o bá rí ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ, mú un.” Jakọbu kò sì mọ̀ pé, Rakeli ni ó jí àwọn òrìṣà náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.