Gẹnẹsisi 31:28
Genesis 31:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ kò tilẹ̀ jẹ́ kí èmi fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ mi lẹ́nu, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mi pé ó dìgbà? Ìwọ ṣiwèrè ní ohun tí ìwọ ṣe yìí.
Genesis 31:28 in English
Genesis 31:28 · Berean Standard Bible
But you did not even let me kiss my grandchildren and my daughters goodbye. Now you have done a foolish thing.
Context
26Nígbà náà ni Labani wí fún Jakọbu pé, “Èwo ni ìwọ ṣe yìí? Tí ìwọ sì tàn mi, ó sì kó àwọn ọmọbìnrin mi bi ìgbèkùn tí a fi idà mú. 27Èéṣe tí ìwọ yọ́ lọ tí ìwọ sì tàn mi? Kí ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé ìwọ ń lọ, kí èmi fi ayọ̀ àti orin, pẹ̀lú ìlù àti ohun èlò orin sìn ọ́. 28Ìwọ kò tilẹ̀ jẹ́ kí èmi fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ mi lẹ́nu, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mi pé ó dìgbà? Ìwọ ṣiwèrè ní ohun tí ìwọ ṣe yìí. 29Mo ní agbára láti ṣe ọ ni ibi, ṣùgbọ́n ní òru àná, Ọlọ́run baba rẹ sọ fún mi pé, kí èmi ṣọ́ra, kí èmi má ṣe sọ ohun kan fún Jakọbu, ìbá à ṣe rere tàbí búburú. 30Nísinsin yìí, ìwọ ti lọ nítorí ìwọ fẹ́ láti padà lọ sí ilé baba rẹ, ṣùgbọ́n èéṣe tí ìwọ fi jí àwọn òrìṣà mi?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.